Aarẹ Ayọdeji Babalọla yoo joye Balogun Agbẹ nijọba ibilẹ Ido, nipinlẹ Ọyọ


Ohun to ṣe pataki ni pe ibi tabi agbegbe teeyan ba wa, ko jẹ ki iwa ọmọluabi jẹ gboogi lọkan ẹ, nitori ko si nnkan mii bi ko ṣe kawọn araye le ma ro nnkan rere ko o.

Idi niyii tawọn ara ijọba ibilẹ Ido, to wa niluu Ibadan, nipinlẹ Ọyọ ṣe pinnu lọkan wọn lati fi Aarẹ Ayọdeji Babalọla, Aarẹ Aṣipa tiluu Odo-nla joye Balogun fawọn agbẹ.

Gẹgẹ bi atẹjade ti wọn fi sita, ayẹyẹ ifinijoye ọhun yoo waye lọjọ Abamẹta, Satide, to n bọ yii, iyẹn ọjọ keje, osu kọkanla, ọdun yii, ninu ọgba ijọba ibilẹ Ido, niluu Ibadan, bẹrẹ ni deede aago mẹwaa aarọ.

Aarẹ Babalọla to jẹ oludasilẹ ileeṣe iṣegun ibilẹ Jasher Spritual Production, ileeṣẹ iṣegun to n ṣe ọmọ araye loore, to wa lagbeegbe Ọjaaba, niluu Ibadan, lo sọ pe oun ti wa nimurasilẹ fun ifinijoye ọhun.

Gẹgẹ bo ṣe wi, inu oun dun lati joye ọhun, ni eyi to tun ni ṣe pẹlu agbẹ. O sọ pe latilẹ loun funra oun ti nifẹẹ si agbẹ, toun si ti fi aimọye ọdun sẹyin da oko.

Jasher ṣalaye siwaju pe oye ọhun yoo tun jẹ ki oun tubọ tẹsiwaju lati mu idagbasoke ba iṣẹ agbẹ nijọba ibilẹ naa paapaa julọ niluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ ati jakejado orileede yii.

A gbọ pe Baalẹ awọn agbẹ nijọba ibilẹ ọhun Oloye Biliaminu Ọlatunji Apanpa ati Ọba Gbọlagade Muritala Babalọla, Gbadewọlu I, Onido tiluu Ido yoo wa
 nibẹ lọjọ naa.

A o ranti pe lọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹjọ, ọdun ta a wa yii ni Baalẹ Odo nla fi Oloye Babalọla joye Aarẹ Aṣipa ilu naa, eyi to waye ni agbegbe Idi Ayunrẹ, niluu Ibadan.

Ni bayii, oloye tuntun ti wa fi tayọtayọ pe awọn eeyan sibi ifinijoye ọhun

Post a Comment

0 Comments