Lojo kerin osu kinni odun yi ni Baale, Igbimo ilu ati Omo ilu Keesan Orile te peepe ayajo Keesan Orile eleyi ti je akotun iru re lati aimoye odun seyin wa.
Ninu Baale ilu naa Oloye AbdulWaheed Abodunrin Abiodun Adeyemi kesi Ijoba Ipinle ati Ibile lati gboro ilu naa ro nipa atunse oju ona pelu sise afara sori abawolu naa. Baale wa sapejuwe oju ona yi gegebi eleyi ti o je pakute idena idagbasoke ilu naa, nitori wipe opolopo ire oko awon agbe ni o maa nbaje soko won nigbati won ko ba le ko lo soja, bee sini awon onira paapaa nsa nilu naa nitori aiko dara ona yi.
Baale tesiwaju wipe Igbimo ilu naa ti bere ise riri opo ina monamona ki awon olokowo le wa se idasile okowo won sibe, idi sini eyi ti awon fi ngbowo ebe si Ijoba lati boju aanu wolu naa fun atunse si oju ona won .
Baale Adeyemi soo di mimo wipe laarin odun kan abo ti awon gba isakoso olori ilu naa atunse ti ba ile iwosan , ile eko, ipese omi ero pelu ohun amayederun nilu
0 Comments