OLUDARI ILE ITURA MOTUN GBORIYIN FUN OBA ORUNDA TILU OLORUNDA.

          Agba oje onile itura kan eyi ti o fikale  silu OLORUNDA ni ijoba ibile Ariwa Abeokuta Alagba Adesina Adejumo ti sapejuwe Oba Olusegun Joshua Enitan Philip Ogunsola  Orunda tilu Olorunda gegebi eniti eledumare ransi ilu OLORUNDA  lati wa gbee soke.
      Alagba Adejumo se alaye wipe aimoye ise idagbasoke lo ti  wolu wa , ti alaafia sii njoba yika ilu naa, awon odo ti nfa wahala to dawo re duro nitori ife ati oyaya ti oba naa fi ko won mora.
      Oludari Ile itura Motun naa wa kesi ijoba apapo lati wa ba won se atunse si oju ona Abeokuta Olorunda si lmeko, ki won seto ti yoo derun fun ara ilu.
       Lakotan, Alagba Adejumo kesi gbogbo Omo Olorunda nile ati leyin odi lati gbaruku ti oba Ogunsola ati igbimo ilu fun ilosiwaju otun.

Post a Comment

0 Comments