Isakoso IJOBA IPINLE yi labe Omo oba Dapo Abiodun Gomina Ipinle yi ti je ko di mimo wipe abo EMI pelu dukia, alaafia ati ifayabale Okan lo je isakoso naa logun nipa idi eyi ni won fenuko ninu ipade won laipe yi se agbekale abadofin merin lati fi ranse sile igbimo Asofin fun agbeyewo ki o si di amulo ofin ni Ipinle yi, awon abadofin naa ni iwa ipanle, jagidijagan, ipaniyan, ajinigbe, egbe okunkun, idaluru ati beebe lo.
Alabojuto fun eto ofin ati idajo Oluwasina Ogungbade SAN se alaye wilpe awon ofin wonyin ni yoo tunbo mu idurosinsin eto abo rinle pelu ifopin si opolopo iwakiwa ti o ba nwaye ni Ipinle yi, bakanna ni Koni si aye fun awijare fun enikeni lati JABO ninu iwa tiri eni bee bahu lawujo , ti yoo si jeya re labe ofin.
Alabojuto naa tesiwaju wipe awon ofin yi ni yoo le awon kolosi eda jina Ipinle yi,ti ko sini da eto alaafia ilu ru eyi ti Gomina wa Omo oba Dapo Abiodun se agbekale re paapaa julo lori awon olokowo lati Ile okere idalesesile pelu awon oludokowo labele wa.



0 Comments