Alake tile Egba Oba Adedotun Aremu Gbadebo ti gba gbogbo awon oloselu lamoran lati je ki alaafia joba lasiko ipolongo ibo, ojo idibo ati leyin re. Oba Gbadebo moro amoran yi waye lasiko iforowero pelu awon akoroyin lede Yoruba ti won kan si oba alaye naa afin nilu Abeokuta laipe julo yi.
Oba Gbadebo kesi gbogbo awon asiwaju oloselu lati maa Faye gba alaafia , ki won si yago fun ariyanjiyan ti o le mu rogbodiyan waye, bi oludibo ba siti dino re tan ki won pada sile lo maa reti esin ibo won, ki olukuluku si to pa ofin idibo mo lojo naa , odo ti o ba to odun mejidinlogun pelu kaadi idibo re lowo ni o le lo sibudo idibo lojo naa
Oba alaye naa wa lo asiko yi lati kesi gbogbo ara ilu lati kora won njanu, ki won si fomo won leti mora.Alake Egba wa to gbogbo awon odo ki won kawe won tan pelu iwe eri ti o duro lowo won ki won to gbera gbalu okere lo eyi ni yoo fun ni anfani lati teete rise nibe.
Lori asotele ipo ona tile Egba wipe bi oba Egba ba pe mewa Ile Egba yoo yato pelu idagbasoke otun , oba naa so wipe eleyi ti wa Nile ti enikeni kosi le yii pada, awon sini olorin Kaye lati wa lori ite gegebi Alake tile Egba kewa, asotele naa sii nwaye nitoripe lojojumo ni orisirisi idagbasoke otun nwolu Egba wa
Lakotan, oba. Gbadebo wa gbe osuba fun agbekale akoroyin lede Yoruba ti o waye yi gegebi wipe Ako fe ki asapelu siso ede Yoruba dohun igbagbe Nile kaaro oojiire. Oba naa ro wa lati tunbo tesiwaju.



0 Comments