E LO EKO INU AWE RAMADAN FUN AKOMONA YIN. GOMINA ABIODUN GBA MUSULUMI IPINLE OGUN LAMORAN.

Gomina Ipinle yi Omo oba  Dapo Abiodun ti ba gbogbo musulumi Ipinle yi yo ayo odun itunu awe pelu adura wipe opolopo odun ni won yoo se laye ati ni aye rere.  

Ninu ise ekun ewu odun ti Gomina fi sita nilu Abeokuta  ni Omo oba Abiodun ti kesi gbogbo musulumi lati lo awon  eko Inu awe Ramadan yi fun AKOMONA won, ki won si muu ni okunkundun lati rii wipe eko yi nsise ninu igbe aye won, eleyi  ni yoo je anfani gbigba awe yi pelu ijiyin ise lojo agbengbe alukiyamo.

     Gomina Abiodun wa dupe lowo gbogbo musulumi fun bi wonti se  ngba adura losan lori fun alaafia idurosinsin ati idagbasoke isakoso yi ni Ipinle ati apapo, eyi ti o je wipe ifowosowopo ati ajosepo ti o duro wa laarin musulumi fun itesiwaju ijoba oselu awaarawa yi.

      Gomina Abiodun wa seleri wipe isakoso oun yoo tunbo maa se agbekale eto ti yoo wa fun igbayegbadun ati idagbasoke Ipinle yii leka  oro aje, eto eko, ilara,awon odo ati beebe lo.

Post a Comment

0 Comments