Bi Ọnarebu Ladi Adebutu ba di Gomina ipinlẹ Ogun, opin yoo deba ipenija awọn oṣiṣẹ fẹyinti-Ọjọgbọn Iyabọ ỌbasanjọOludije fun ipo aṣofin agba fun agbegbe Ogun Central labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP, Ọjọgbọn Iyabọ Ọbasanjọ ti muu dawọn to ti fẹyinti lẹnu iṣẹjọba loju pe didun ni ọsan yoo so fun wọn bi wọn ba le dibo Ọnarebu Ladi Adebutu gẹgẹ bi Gomina lọdun 2027.Lakooko tawọn ẹgbẹ oṣiṣẹ fẹyinti tijọba ibilẹ lorileede yii ẹka ipinlẹ Ogun ṣe ipade pọ pẹlu ẹ.O fi aiduunu ẹ han lori bawọn isakoso to ti kọja atawọn to wa nibẹ ṣe kuna lati maa mu inu awọn eeyan ọhun lẹyin ti wọn ti sin tọkantọkan.Ọbasanjọ sọ pe oun to buru ni pe ẹtọ awọn oṣiṣẹ to yẹ ki wọn maa jẹ ninu ilera pipe ni wọn ki i tete san fun wọn bọrọ.Iyabọ Ọbasanjọ kọkọ gboriyin fawọn ọmọ ẹgbẹ ọhun fun ẹmi ifarajin wọn lakooko ti wọn wa lẹnu iṣẹ, amọ o kẹdun lori ipenija ti wọn koju lori awọn nnkan to jẹ mọ ẹtọ wọn.O ṣalaye pe ibanujẹ lo jẹ foun bawọn ijọba to ti kọja ṣe n foju awọn oṣiṣẹ fẹyinti ọhun to jẹ pe gbogbo ẹtọ wọn to yẹ ki wọn maa fi gbadun lẹyin ti wọn fiṣẹ silẹ, ni wọn tun fi ni wọn lara.Oludije fun ipo aṣofin fun ẹkun Ogun Central tun fi kun ọrọ ẹ pe owo awọn oṣiṣẹ fẹyinti ki i ṣe nnkan to yẹ ki wọn fọwọ kan, o lo yẹ ki wọn maa san fun wọn lakooko, nitori iyẹn ireti ayọ pe wọn jẹ igbadun lẹyin ti wọn fi iṣẹ silẹ, nigba ti wọn ṣi wa laaye ati alaafia.Iyabọ Ọbasanjọ waa mu dawọn loju pe igbesẹ mii in yoo wa ti yoo si ṣee ṣe iyẹn ti wọn ba dibo fun un gẹgẹ bi aṣofin agba fun ẹkun Ogun Central, ti wọn si tun dibo fun Ọnarebu Ladi Adebutu, gẹgẹ bi gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP.Nigba to n sọ idi pataki to fi muu pada sidi oṣelu, Aṣofin agba Ọbasanjọ sọ pe oun pada latari bawọn eeyan ṣe n gboriyin fawọn iṣẹ toun ti ṣe ati kiko ara ẹni nijanu, atawọn ipa ribiribi toun ti ko lakooko to fi jẹ kọmiṣanna feto ilera ati aṣofin agba niluu Abuja. Pẹlu ileri pe oun yoo tubọ le ṣe ju bẹẹ lọ, bi wọn ba le dibo yan oun wọle lọdun 2027.O ni ero ọkan oun lati pada dije ni lati sin awọn eeyan ipinlẹ Ogun tọkantọkan, ki i ṣe nipa imọtara ẹni ni kan bi awọn kan.Iyabọ Ọbasanjọ sọ pe nnkan ti oun mọ ni pe gbogbo nnkan to ba jẹ ti alumọni ati ọrọ ilu ni awọn gbọdọ naa sapo ilu. Nigba to n sọrọ, alaga fawọn oṣiṣẹfẹyinti naa fun Abẹokuta South ati Abẹokuta North, Alaaji Sulaiman Gbọlagade, o gboriyin fun Iyabọ Ọbasanjọ fawọn ipa ribiribi to ti ko nigba to fi wa nipo kọmiṣanna feto ilera.O ṣapejuwe ẹ gẹgẹ bi ọmọluabi to fọkan jin nigbogbo akoko ọhun eyi tawọn akọsilẹ rẹ rere ṣi wa.Ipade ọhun tun faye silẹ fawọn oṣiṣẹ fẹyin ọhun lati sọ ẹdun ọkan wọn ti wọn ti n foju wọn winna tipẹ ti wọn si ṣalaye ẹ fun Ọjọgbọn Iyabọ Ọbasanjọ.

Bi Ọnarebu Ladi Adebutu ba di Gomina ipinlẹ Ogun, opin yoo deba ipenija awọn oṣiṣẹ fẹyinti-Ọjọgbọn Iyabọ Ọbasanjọ

Post a Comment

0 Comments