OTUNBA JIMI LAWAL DI ADIJE GOMINA FUN EGBE OSELU ADC NINU ETO IDIBO 2027.


Gẹgẹ bi a ṣe mọ pe titi di akoko ta a wa yii nnkan ko rọgbọ laarin ẹgbẹ oṣelu APC ati PDP nipinlẹ Ogun, ojoojumọ lawọn mejeeji n ko ara wọn jade bi ọjọ mẹjọ, to si jẹ pe wahala ti wọn n ba ara wọn fa ko jẹ ki wọn raye jẹ kawọn araalu mọ nipa nnkan ti wọn ni fun araalu.

Ni nnkan bii oṣu meloo kan sẹyin nigba ti wahala abẹnu n waye ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, ti ọrọ ara wọn ko ye ara wọn, ẹgbẹ kan ṣoṣo tawọn eeyan nigbagbọ bi alatako ni African Democratic Congress iyẹn ADC.

Ṣugbọn nigba ti yoo di inu oṣu kẹrin ọdun 2026, nibi ipade gbogboogbo to waye nnkan ti bẹrẹ si ni daru, ti akara ti fẹẹ maa tu si epo,bo tilẹ jẹ pe awọn igun kan ṣe idibo alabẹṣekele taa mọ si pamari lọna ti ofin la kalẹ fun wọn, nibi ti wọn ti ṣeto ibo fawọn ipo ti wọn dije fun, eyi tawọn olori wọn lapapọ atawọn eleto idibo wa nibẹ pẹlu.

Nigba ti wọn yoo si fi kede oludije gomina nibi ibo pamari lọjọ kejilelogun, oṣu karun-un, ọdun yii, ṣe ni awuyewuye miii tun bẹrẹ.

Pẹlu gbogbo ọna ti ADC gba lati yanju ọrọ naa ni abẹlẹ ni ko so eso rere, eyi to jẹ ki wọn pade ara wọn nile ẹjọ.

Ṣugbọn nigba ti yoo di ọjọ kẹtalelogun, oṣu keje, ọdun yii ni idajọ kan waye nile ẹjọ giga apapọ to wa niluu Abẹokuta, nibẹ ni wọn ti da Ọtunba Jimi Lawal lare gẹgẹ bi oludije gomina fẹgbẹ oṣelu ADC.

Idajọ ọhun ko tẹ awọn alatako ẹ lọrun, ni wọn ba tun gba ile ẹjọ kotẹmilọrun lọ,ṣugbọn tawọn da ẹjọ naa nu patapata, lọjọ kejidinkogun, oṣu kẹsan- an, ọdun yii.

Gbogbo bi Solomon Ọlalekan Adeọla, Yayi ti APC ati Ladi Adebutu tẹgbẹ oṣelu PDP, ṣe n fojoojumọ fi oko ọrọ ranṣẹ si ara wọn lori ọmọ ilu ati bi Ipẹru kan tun fẹẹ gbajọba lọwọ Ipẹru ẹgbẹ ẹ bẹẹ ni Jimi Lawal dakẹ jẹ, to n ba iṣẹ tiẹ lọ pẹlu awọn araalu pẹlu awọn eto to ni.

Ọpọ awọn ti oye oṣelu ye ni wọn sọ pe anfaani to pọ lo wa fun lati jawe olubori.Akọkọ si ni ti ija to n waye laarin Yayi ati Ladi Adebutu.

Ẹlẹẹkeji si ni ilẹ Ijẹbu to ti wa, ti wọn ko ni anfaani mii mọ lati ọdun 1983 ti Oloye Ọnabanjọ tii jẹ gbẹyin. Iyẹn ni nnkan bii ọdun mẹtalelogoji sẹyin.

Pẹlu awọn oye nla meji to tun ti jẹ nilẹ Ijẹbu iyẹn Ajirọba ati Olootu Iforẹ Akilẹ Ijẹbu, eyi ti Awujalẹ to waja, Ọba Sikiru Adetọna fi jẹ.

Jimi Lawal ni wọn tun ri gẹgẹ bi ọmọ ijẹbu ti wọn n reti ni Oke-Mọsan,oun si tun ni Giwa Adinni mọṣalasi nla ni Ijẹbu Ode.

Pẹlu gbogbo eleyii awọn ilana eto marun-un to ni tun eyi ti yoo tan kan gbogbo to wa nipinlẹ Ogun.

Lati ori idagbasoke ọrọ aje titi de imayedẹrun, aabo ati iṣakoṣo iṣejọba rere fun mutumuwa ọmọ ipinlẹ Ogun.

Nipa ilana iṣejọba rere gbogbo ẹ ni Jimi Lawal ni nipaṣẹ ifọkantan lati maa fi owo to jẹ tijọba ibilẹ sinu apo oṣuwọn wọn taara gẹgẹ bi ile ẹjọ to ga julọ ṣe paa laṣẹ, ati idibo ijọba ibilẹ ti ko nii mu ojuṣaaju wa, iru eyi to waye nipinlẹ Kaduna, nibi to ti jẹ Oludampran pataki lori idagbasoke ọrọ aje.

 Bi Jimi Lawal ti ṣe wa n gbaradi bayii lati jade sita gbangba fun ipolongo laipẹ yii pẹlu ọrọ akọle ' Jẹ ki ipinlẹ Ogun tun ga si'  Ṣe lọkan awọn alatako ko balẹ mọ.

Post a Comment

0 Comments