Lojo kejidinlogun osu kejo odun yi ni Obinrin Akoko lori ede yi Asofin Agba Oluremi Tinubu se ifilole ibudo ounje ofe fun awon Omode bere lati osu mefa si odun mefa nilu Abeokuta eleyi ti o wa fun ekun Iwo oorn Orile ede yi.
Aya Are Tinubu Soo di mimo wipe eleyi lo muu di ekun kerin. Asofin Agba Remi Tinubu se alaye wipe eredi eto yi ni ki awon Omode pelu iya ati alaboyun le je anfani oselu awaarawa.
Oludasile eto yi wa ro gbogbo awon Gomina Ipinle kookan lati gbaruku ti eto yi ki won si je ki ljoba ibile kookan ni ibudo pelu woodu kookan nipa idi eyi ni akori eto se FIDI kale si Ile iwosan alabode ni woodu kookan.
Lojo yi Kanna ni Oluremi Tinubu si Buhari Estate, Gateway Medical Centre Okemosan Abeokuta. Won gboriyin fun Gomina Abiodun fun ise IDAGBASOKE to kale si Ipinle yi.
Ninu oro re nibe Omo oba Dapo Abiodun Gomina Ipinle Ogun dupe lowo Are Tinubu fun mimu Orile ede yi tesiwaju. Gomina wa muu da oludasile eto yi wipe eto naa yoo kesejari ni Ipinle yi.
Gomina Abiodun se alaye wipe Ijoba Ipinle yi ti atunse si opolopo Ile iwosan alabode ni woodu kookan ki won kaju osuwon ipenija ode oni yi.



0 Comments