Ọpẹ o! Wọn ti bẹrẹ sii wa epo rọbi ni ipinlẹ Ogun


Ọlawale Ajao, Ibadan

Ipinlẹ Ogun ko nii pẹẹ di ọkan ninu awọn ipinlẹ to lowo julọ ni Naijiri bayii pẹlu bi wọn ṣe ti bẹrẹ sii wa epo rọbi ni ipinlẹ naa bayii lẹyin ti wọn ti ṣawari ohun alumọọni ọhun lọna meji ọtọọtọ nibẹ.

Oludamọran fun Ọmọọba Dapọ Abiọdun tii ṣe Gomina Ipinlẹ Ogun lori Eto Iroyin ati Ọgbọn  Atinuda, Ọgbẹni Kayọde Akinmade lo fìdí iroyin yii mulẹ lasiko to gba awọn to n fi ede Yoruba kọroyin ni ipinlẹ Ogun lalejo lọfiisi ẹ, nileeṣẹ ijọba to wa lOke Mọsan, lAbẹokuta, ni ipinlẹ Ogun lỌjọruu, Wẹsidee, Ọjọ Kẹjọ, Oṣu Keje, Ọdun 2026 yii.

O ni  "Inu mi dun latii sọ fun gbogbo aye pe ijọba ti n wa epo rọbi ni Erékùṣù Ẹ̀bà, ni ipinlẹ Ogun.

"Nigba ti Gomina ṣi ọna kan lagbegbe Waterside ni nnkan bii ọsẹ meji sẹyin, wọn fi ye wa pe lati agbegbe Ijẹbu, de Odogbolu, ilẹ to wa ni gbogbo ibẹ, kiki epo rọbi ni, epo rọbi ti ko ni odiwọn. 

"A ti gbe ìgbesẹ akọkọ bayii lati ri i pe ipinlẹ Ogun di ọkan ninu awọn ipinlẹ to n pese epo rọbi lorilẹ-ede yii."

Ṣaaju ni wọn ti ṣawari epo rọbi lagbegbe Ẹ̀bà, nijọba ibilẹ Ipokia, ni ipinlẹ Ogun, ti wọn sì ti bẹrẹ síi wa ohun alumọọni naa nibẹ bayii.

Nigba to n sọrọ nipa aṣeyọri Gomina Abiọdun laarin ọdun meje to ti wa lori àpèrè ijọba ipinlẹ Ogun, Ọgbẹni Akinmade ṣalaye pe ori opo marun-un, eyi ti wọn kọ silẹ lede Oyinbo, ṣugbọn ti ìgékúrú rẹ̀  n jẹ "IṢẸYA" lede Yoruba, ni Gomina Abiọdun gbe eto iṣejọba rẹ le lori.

O ni ohun ti IṢẸYA tumọ si ni ipese awọn ohun amayedẹrun, eto aabo, eto ẹkọ, idagbasoke awọn ọdọ ati igbelarugẹ eto ọgbin, ati pe lori awọn eto maraarun wọnyi ni ijọba gomina naa ti wẹ yan kain-kain bayii.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, "Gbogbo wa la mọ pe taa ba ṣe gbogbo oju titi, taa da ọda si gbogbo ẹ, ti ko ba si eto aabo, ko nii si alaafia ati ifọkanbalẹ, ko si nii sẹni to maa waa da ileeṣẹ silẹ nitori awọn araalu ko nii maa gbe pẹlu alaafia."

Lori eto aabo, Ọgbẹni Akinmade ṣalaye pe "Lati ọdun  2019, ni saa akọkọ Gomina Abiọdun, ti awọn agbesunmọmi ti ji awọn to n lọ síbi eto ijọ Ridiimu gbe, ni Gomina ti so okun eto aabo le dan-in-dan-in. 

"Nitori iṣẹlẹ yẹn ni Gomina Abiọdun ṣe lọọ ba Aarẹ Muhammadu Buhari nigba naa, ti ijọba apapọ fi gbe ọkọ ofurufu fun ipinlẹ Ogun. 

"Ọkọ ofurufu yẹn ni wọn fi wa awọn agbesunmọmi yẹn kan, taa fi ri wọn mu laarin ọjọ meji pere. Anfaani akitiyan ti Gomina Abiọdun ṣe lori eto aabo nigba yẹn la n jẹ titi di asiko yii, to fi jẹ pe ipinlẹ Ogun ko si ninu awọn ipinlẹ to n koju wahala awọn agbesunmọmi bayii.

"Alaafia to jọba ni ipinlẹ yui lo fa a to fi jẹ pe ni gbogbo Naijiria, ipinlẹ Ogun lawọn ara ilẹ okeere maa wa julọ lati da ileeṣẹ silẹ."

O fi kun un pe "Aṣaaju ni ipinlẹ Ogun jẹ lori eto ẹkọ. Eyi ko ṣeeṣi ri bẹẹ rara. Yatọ si pe ipinlẹ yii lo ni ileewe gíga to pọ julọ ni Naijiria, ijọba Dapọ Abiọdun ti mu idagbasoke ba eto ẹkọ dẹbii pe, Gomina le mu ẹrọ ibanisọrọ lọwọ bayii, ko wo iye akẹkọọ to wa ni kikaasi kọọkan, akẹkọọ kọọkan lo si ti ni nọnba idanimọ. 

"Ijọba ṣe eyi lati le maa mojuto eto ẹkọ, lati ri i daju pe awọn akẹkọọ n ṣe daadaa lẹnu ẹkọ wọn ni."

Gateway International Airport ti Gomina Abiọdun kọ sí ipinlẹ Ogun jẹ ara nnkan ti awọn ara ipinlẹ Ogun yoo fi maa ranti ijọba rẹ titi laelae.

Baa ṣe n wi yii, idagbasoke to ti wọ agbegbe yẹn kii ṣe kekere. Beeyan ba mu miliọnu lọna aadọta Naira (₦50m) lọwọ, ko le ri ilẹ pulọọti kan pere ra nibẹ bayii. Ṣe ẹ ri i pe awọn to ni ilẹ lagbegbe yẹn ti ṣoriire."

O waa ṣeleri atilẹyin ijọba ipinlẹ Ogun fun awọn akọroyin lede Yoruba, o ni igbelarugẹ aṣa ati iṣe Yoruba jẹ ijọba paapaa logun.

Post a Comment

0 Comments