Ojuse gbogbo wa ni lati gbe ede ati asa wa laruge- Oloye Segun Sowunmi.

Orileede to ba sọ ede rẹ nu ti sọ idanimọ rẹ nu atipe yoo dabii orileede ti ko ni ẹyin ọla ni', Orọ yii ni gbajumọ oloṣelu, Oloye  Ṣẹgun Ṣowunmi sọ lasiko ti ẹgbẹ oniroyin lede Yoruba, 'League of Yoruba Media Practitioners', ẹka ipinlẹ Ogun ṣabẹwo si i nilẹ rẹ nilu Abẹokuta.

Ṣowunmi jẹ ko di mimọ pe bawọn obi ati alagbatọ ba kuna lati jẹ kawọn ọmọ wọn maa sọ ẹdẹ Yoruba, o ṣee ṣe kawọn ọdọ iwoyi koju iṣoro lọjọ iwaju latari bi  wọn ko ṣe fẹran lati maa sọ ede abinibi wọn. O ni, ọrọ naa ko yọ awon olukọ paapaa silẹ, ṣe ni ki wọn mu kikọ ati sisọ ede abinibi wa ni pataki ni yara ikẹkọọ.

Eekan oloṣelu naa waa rọ gbogbo ẹka igbohunsafẹfẹ ati iwe iroyin lati maa ṣe igbelarugẹ ede ilẹ kaarọ oojiire nigba gbogbo.

Sowunmi  gbe oṣuba o kare fawọn ọmọ ẹgbẹ naa fun igbiyanju wọn lati ri i daju pe, ede naa ko lọ soko igbagbe.

O tun lo asiko naa lati rọ aarẹ orileede Naijiria, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu lati tubọ fẹsẹ  imọ ẹkọ ede Yoruba mulẹ siwaju si i lawọn ileewe kaakiri ilẹ kaarọ oojiire.

Ṣowunmi tun gboṣuba kare fun Aarẹ Tinubu fun awọn iṣẹ akanṣe aritọkasi to ti ṣe paapaa lẹka awọn ohun amayedẹrun.

Gẹgẹ bi ọrọ rẹ, 'Bi ija ba wa nibẹ ka pari  ẹ, Tinubu ṣiṣẹ to lapẹẹrẹ, eyi tawọn eeyan ma ranti fun ọdun pipẹ'. O mẹnuba aṣeyọri aarẹ lori ọrọ atunṣe owo ori, eyi to mu igbaye irọrun ba awọn mẹkunnu, yiyọ owo iranwọ epo lati ṣe iṣẹ akanṣe kaakiri awọn ipinlẹ, pipese owo iranwọ fawọn akẹkọọ iyẹn NELFUND ati bẹẹ bẹẹ lọ.
                                    
O gba awọn ọmọ ilẹ kaarọ oojiire nimọran pe ki wọn ma ṣe pẹlu awọn atọhunrin kọyin sọmọ ti wọn nitoripe tẹni-n-tẹni.

Ṣowunmi sọ pe, iṣẹ pọ fun Aarẹ Tinubu lati ṣe, nitori naa lo ṣe gbọdọ lo ọdun mẹjọ rẹ pe.O ni gbogbo ọmọ Yoruba lo gbọdọ ṣatilẹyin fun Tinubu fun itẹsiwaju rere.

Post a Comment

0 Comments