Gomina Abiọdun gboṣuba fun Aarẹ Tinubu lori idasilẹ ọlọpaa ibilẹ.


Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdu ti fi igbagbọ ẹ han pe awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin to wa kaakiri ipinlẹ lorileede yoo gba aba idasilẹ lori awọn ọlọpaa ibilẹ wọle, nitori oun nikan lọna abayọri sawọn isoro to n dojukọ eto abo to mẹhẹ.

O sọrọ yii nigba to n kopa nibi eto tẹlifisan, ipade ilu,o ni igbesẹ ti n lọ lọwọ lori ọna bi idasilẹ ọlọpaa ọhun yoo ṣe di amulo. O wa
 gboriyin fun Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu lori bi ko ṣe fọrọ naa falẹ, to si gbe iwe aba naa ranṣẹ sile igbimọ aṣofin lati le tete buwọ luu.

O ṣapejuwe ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹfa, ọdun yii gẹgẹ bi  ọjọ manigbagbe ninu itan ijọba tiwa-n-tiwa.O ṣakiyesi pe o jẹ ayajọ idapada ofin awọn alaṣẹ ilẹ wa lori idasilẹ ọlọpaa ibilẹ sọdọ awọn aṣofin agba lati le fọwọ si.

Gẹgẹ bo ṣe wi, o nijọba to kogba sile gbinyanju lati da a silẹ ṣugbọn ti wọn ko rii ṣe, ṣugbọn tijọba akoko yii ṣaseyọri ẹ, o ni oriire nla ni.

Gomina Abiọdun ṣalaye siwaju pe, "Mo dupẹ lọwọ ileeṣẹ tẹlifisan Arise, fun eto nla ti wọn ṣagbekalẹ ẹ yii. O ti wa di itẹwọgba gbogbo awọn araalu nitori bo ṣe n ṣafihan ọrọ to ba n jẹ awọn araalu lọkan. Lara nnkan to jẹ itẹwọgba araalu ni idasilẹ ọlọpaa ibilẹ."

Gomina Abiọdun to tun jẹ alaga igbimọ lori idasilẹ ọlọpaa ibilẹ tun ṣalaye wi pe gbogbo awọn gomina lorileede yii lo ti kopa to jọju lori bi aba naa yoo ṣe di amulo, nitori wọn mọ ipa to le ko ninu ijọba.

O ni bo tilẹ jẹ pe awọn gomina ipinlẹ kọọkan ni olori alaabo ilu amọ o nibi ti agbara wọn de ninu eto ofin inawo lati ṣatilẹyin fun idasilẹ yii.

Abiọdun tun fikun ọrọ ẹ pe ẹgbẹ awọn Gomina lorileede yii ṣagbekalẹ igbimọ kan lati ṣiṣẹ pọ pẹlu olori eto idajọ lawọn ipinlẹ atawọn aṣofin lori idagbasoke aba naa.

Bẹẹ lo sọ pe ara anfaani ti yoo tun mu ba idasilẹ ọlọpaa ibilẹ ni pipese iṣẹ kaakiri fawọn eeyan.

O waa fi tipinlẹ Ogun ṣe apẹẹrẹ, o ni ẹgbẹrun mẹfa lawọn oṣiṣẹ alaabo tipinlẹ ti wọn gba kaakiri ipinlẹ naa, iyẹn Amọtẹkun, So Safe, fijilante atawọn mii in, o ni iru awọn bẹẹ naa lo wa kaakiri awọn ipinlẹ kọọkan, eyi to sọ pe o tumọ si pe bii ẹgbẹrun lọna ọọdunrun si irinwo afikun alaabo lo wa lorileede yii.

O ni pẹlu igbesẹ yii yoo jẹ ki eto aabo gun rege tawọn araalu yoo si wa ni ifọkanbalẹ.

Post a Comment

0 Comments