Ọga agba fajọ eleto abo nipinlẹ Ogun iyẹn Ogun StateCommunity, Social Orientation and Safety Corps, ti ọpọ mọ si So-Safe Corps, Oluṣọji Ganzallo, ti sọrọ lori bi ipinlẹ Ogun ṣe n ṣe aṣeyọri lori eto abo.
O ni ko si ọgbọn alumọkọroyii kan tawọn n da bi ko ṣe ifiọwọsowọ pọ lati ri daaju pe eto abo ko mẹhẹ ni ipinlẹ Ogun.
Ganzallo sọ eyi lọjọ Iṣẹgun Tusde yii lakoko ipade ifọrọwerọ pẹlu awọn oniroyin Yoruba, to waye ni oluleeṣẹ So-Safe Corps ni Abeokuta.
O ni oun to dara ju ni pe ki eleto abo ma ko ju ipenija ko to di ogun, oni ki eeyan dena wahala dara ju ko maa wa ojutu sii lọ lẹyin to ba sẹlẹ.
Ọga agba naa sọ ẹdun ọkan lo jẹ pe awọn eeyan ki i gbe oriyin fun ajọ eleto abo ti wọn ko ba mu ọ̀daran tabi ti iṣẹlẹ laabi o ba ṣẹ.
O ṣalaye pe ileeṣẹ eleto abo ipinlẹ Ogun ma ko rawọn jọ lati rii daaju pe wọn dena ọran ṣaaju ko to ṣẹlẹ nitori ẹ̀mí awọn eeyan wọn ṣe pataki.
Ganzallo wa sọ siwaju pe lati ri daju pe ibaṣepọ to danmọran wa pẹlu gbogbo ẹka alaabo ati i pe ipade oloṣoṣu ma n waye pẹlu gbogbo awọn ẹka eto aabo lati ṣe ijiroro ti yoo ṣe iranlọwọ fun abo ipinlẹ naa.
O ni ibasepo yii ko pari si aarin awọn eleto abo ipinlẹ Ogun nikan, ajọ So Safe tun ni ibasepo to danmọran pẹlu ileeṣẹ eleto abo àwọn ipinlẹ ti ipinlẹ Ogun farati bii Ọyọ, Eko ati bẹẹbẹẹ lọ, bẹẹ ni wọn tun ni ibaṣepo pẹlu awọn orile-ede ti ipinlẹ Ogun mule ti
.
Oga agba naa ṣalaye pe ọpọ igba lawọn ọdaran ma n sa lati orile-ede Naijiria lọọ si Bẹnẹ, ṣùgbọ́n ni kete ti awọn ba ti kesi awọn eleto abo orile-ede Bẹnẹ ni wọn yoo ti ṣe awari wọn ti wọn yoo si daa wọn pada fun awọn.
Ganzallo sọ siwaju si pe gbogbo ẹka ni awọn maa n fi ọrọ to leti lati ri pe eto abo wa ni digbiɔ, o salaye pe ti wọn ba fi ọ̀rọ̀ to oun leti tabi wọn jẹ ki oun mọ pe rogbodiyan n ṣẹlẹ̀ ni agbegbe kan, oun yoo pe awọn ọlọpaa agbegbe naa atawọn Amọtẹkun, nitori àjọṣe ni iṣẹ abo nipinlẹ Ogun.
Ninu ọrọ Ganzallo, o tun salaye pe gbogbo awọn oṣiṣẹ So Safe ni wọn ma n gba idanilẹkọ to ye koro ni orekore lọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ninu ọgbà idanilẹkọ ajọ So Safe to wa nilu Ilaro, oni wọn ṣe pari ọkan laipẹ yii ni.
Lori eto aabo ileewe, Ganzallo sọ di mimọ pe ipinlẹ Ogun lo kọkọ ṣeto ki ajọ eleto abo maa wa ni agbegbe awọn ileewe lati dabobo awọn ọmọleewe ati olukọ, tawọn si n ṣe titi di akoko yii
Ganzallo ni eto Ilana ofin aiki gbe owo rin (cashless policy) ti mu ẹdinku ba idigunjale ṣugbọn ijingbe lo gba igboro, fun idi eyi, o gba awọn eeyan lamọran pe ki wọn ye wọ ọkọ sọọlẹ, ki wọn maa ri daaju pe ilẹ mọ daadaa ki wọn to jade nile, ki wọn si ma rin loru.
Ni paapaa ki wọn ye gbe igbesi aye wọn sori afẹ́fẹ́, nitori wọn ko mọ ẹni to n ṣọ wọn.
Bakan naa lo tun gba awọn araalu lamọran pe ki wọn maa dagbere ibi ti wọn ba n lọ fun awọn ololufẹ wọn nile, o tun rọ awọn obi pe ki wọn ṣe amojuto awọn ọmọ wọn lati ri pe wọn jinna si egbogi oloro nitori ipalara nla lo n ṣe fun awujọ wa.
O gbe oṣuba kare fun ajọ awọn oniroyin Yoruba fun ìṣẹ takuntakun ti wọn n ṣe lati gbe iroyin fun awọn eeyan, o ni ajọ So Safe mọ riri iroyin Yoruba nitori ọpọ awọn ti ajọ naa ṣe abo fun ni ìgbèríko ni ko gbọ ede gẹẹsi.
O wa rọ awọn eeyan lati dẹkun ati ma san owo fawọn ajínigbé, o ni ṣe ni wọn fi ro wọn lagbara nipa eyi.



0 Comments