GOMINA ABIODUN SE IPADE PO PELU OLUDARI AJO POWER AFRICA FUN IPESE INA MONAMONA NI IPINLE OGUN.
Laipe julo Yi ni Gomina wa Omo oba Dapo Abiodun se ipade onidagbasoke ilu po PELU awon ajo ti a mo si Power Africa eyi ti won maa nse anfani ipese ina MONAMONA silu,ipade yi waye leyin ti won pari apero ipade African lnveetiment Forum ni Rabat Orile Ede Morocco
Gomina Abiodun se alaye wipe bi ipade alajosepo Yi ba ti so eso rere yoo je anfani ipese ina MONAMONA silu Abule, Ileto , olokowo,ile ise nlanla bee sini oro aje yoo tunbo buyari sii ni lpinle yi, ina monamona yoo si maa wa ni 24/7.
Gomina je ko mimo wipe awon ajo yi ni won maa npese ina monamona seyinseyin wa ni awon ilu Sub-Sahara African.Eyi yoo si agbelaruge ile ise Ijoba to wa fun eroja epo ati agbara ni Ipinle yi.
Gomina Abiodun so teduntedun wipe isakoso oun ni lokan lati mu ipese ina monamona eroja epo pentiro ohun amusagbara duro daradara nitori ile ise ajo elepo ile wa Nigeria National Petroleum Corporation Ltd ti foju si Ipinle yi lara lati je okan lara Ipinle time ni eroja epo robi lowo,nipa idi eyi ni awon se gbodo ta mora ki Ipinle yi paapaa le je okan pataki leka ipese epo pentiro ati eroja miran Lori ede Yi ati lagbaye.
0 Comments