IDIBO 2027, IBO ALAJOBI WOLE DE , OMO IPINLE OGUN E FIBO YIN GBE TINUBU WOLE PADA LEKEJI. ......Otunba Sowunmi Amoran pataki kan ti lo sodo gbogbo omo ati olugbe Ipinle Ogun lati dibo alajobi nipa fifi ibo won gbomo wa nile Yoruba Asiwaju Ahmed Bola Tinubu wole pada sipo Aare Orile Ede yi lekeji. Otunba Segun Sowunmi agbateru The Alternative Movement ti won fii nse atileyin ipolongo fun Aare Tinubu so wipe ibo alajobi ni gbogbo omo Ipinle yi gbodo di fomo wa yi lopo yanturu to sini lati bori eyikeyi ibo ni awon Ipinle miran lorile ede yi ki ale lenu oro lojo ola. Otunba Sowunmi eni to nba ogunlogo eniyan soro nibi akojopo omo egbe The Alternative Movement nilu Itoko Abeokuta kesi gbogbo eniyan wipe "ki eku Ile gbo loso fun toko, ki adan gbo loro fun oode ibo alajobi lo wole de bayi nipa idi eyi enikeni ti o ba nikun sinu ara won lati paati se atileyin fomo wa nile Yoruba. Ogbontarigi oloselu naa wa gbe oriyin fun Omo- oba Dapo Abiodun fun gbogbo agbekale ise idagbasoke otun toba ipinle yi labe isakoso won, ki enikeni mase ba won tabuku Gomina Abiodun, ibi ti won ba fe ka dibo wa si ni ki olukuku fibo re si, ki egbe APC le tesiwaju akoso Ipinle yi.

IDIBO 2027, IBO ALAJOBI WOLE DE ,  OMO IPINLE OGUN E FIBO YIN GBE TINUBU WOLE PADA LEKEJI.
   ......Otunba Sowunmi

Post a Comment

0 Comments