OLOSELU NI IPINLE OGUN, E NI IBERU OLORUN LOKAN.........Alaga IPAC


Alaga ẹgbẹ awọn alaga fawọn ẹgbẹ oṣelu, Inter-Party Advisory Council (IPAC), ẹka tipinlẹ Ogun, Kọmureedi Abayomi Sanyaolu ti sọ pe ẹnikan ṣoṣo to le ṣakoso ipinlẹ naa lai ni kudiẹ-kudiẹ ni ẹni to b ani ibẹru Ọlọrun lọkan.
Kọmureedi Sanyaolu sọ pe ibẹru Ọlọrun nikan ni eeyan le fi ṣakoso ilu lai ni ijakulẹ, ti yoo si maa jẹ ki itẹsiwaju ati idagbasoke wa fun ilu.
Sanyaolu, ẹni to tun jẹ alaga fẹgbẹ oṣelu All Peoples Movement (APM) nipinlẹ naa lo sọ eyi lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ laipẹ yii niluu Abeokuta, ipinlẹ Ogun.
Nigba to n sọrọ, agba oloṣelu naa jẹ ko di mimọ pe ọpọ awọn oloṣelu Naijiria ni wọn ko ni ibẹru Ọlọrun ti wọn fi n dari ilu, ati pe pupọ ninu wọn lo jẹ pe imọ-tara-ẹni-nikan lo jẹ wọn logun.
“A nilo ẹni to ni ibẹru Ọlọrun, nitori pe ẹni to ba ni ibẹru Ọlọrun nikan lo le ṣe gomina wa, kii ṣe keeyan kan maa ko ọrọ jọ lasan. Bawo leeyan yoo ṣe ni ile marundinlaadọta, lori asan ni,” Sanyaolu sọ bẹẹ fawọn akọroyin.
Nigba to n sọrọ lori igbaradi fun eto idibo gomina nipinlẹ Ogun ti ọdun 2027, alaga naa jẹ ko di mimọ pe ohun to ṣẹlẹ nipinlẹ Osun ko nii yatọ si nnkan ti yoo ṣẹlẹ nipinlẹ naa, nigba ti asiko ba de.
“Ipa ti a n ko pọ jaburata, nitori pe a ko duro rara. A ni oriṣiriṣi eto lati rii pe eto idibo 2027 ko dabi eto oṣelu ti a ti n ṣe lati ẹyin wa. Ṣugbọn mo fẹ ki ẹ mọ pe idibo 2027 ko nii yatọ si eyi to waye nipinlẹ Ọṣun laipẹ yii,” alaga fidi rẹ mulẹ.
O ni gbogbo erongba awọn ni lati jẹ ki araalu mọ pe awọn ti w ani imurasilẹ gidigidi, nitori pe ohun to n bọ lọdun 2027, ko nii dabi awọn eto idibo to ti waye kọja lọ.
Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe, “Erongba wa ni pe ki gbogbo eeyan mọ pe a gbaradi loootọ. Ẹgbẹ oṣelu mejilelogun la ni nipinlẹ Ogun, ẹ si maa rii pe ẹgbẹ alatako mura gidi fun eto idibo to n bọ lọna.
“Loootọ ni ẹgbẹ oṣelu APC n sọ pe ko si ẹgbẹ oṣelu alatako, bẹẹ si ni PDP sọ pe ko si ẹgbẹ alatako, ṣugbọn emi mọ pe wọn n tan ara wọn jẹ ni. APC ati PDP, a jọ wa ninu ẹgbẹ IPAC ni.”
Bakan naa nigba to n sọrọ nipa aawọ to n ṣẹlẹ lẹgbẹ oṣelu APC, paapaa lori eto idibo abẹle lati gba tikẹẹti ipo gomina, o ni ẹni ti eto naa ko tẹ lọrun ti wa fi ẹjọ sun, to si lawọn ti wa lori igbesẹ lati wa ọna abayọ to tọ.
“Oludije sipo gomina lẹgbẹ oṣelu APC, Ọnarebu Abayomi Hunye ti wa b awa, to si fi ẹjọ sun pe APC ja oun lole, ara ojuṣe wa niyẹn. Ọpọlọpọ ẹjọ ni ọkunrin naa ro fun wa, a si ti fi da a loju pe a maa gbe igbesẹ to yẹ ka gbe,” ọkunrin naa sọ bẹẹ.
O sọ siwaju pe, “Ẹgbẹ alamọran ni wa, a si maa rii pe ko si aawọ ninu ẹgbẹ oṣelu kankan, nitori pe bi a ko ba ṣọra, ẹgbẹ oṣelu kan ṣoṣo le dana si ilu, nigba ti wọn ba bẹrẹ sii fa wahala.
“Ninu ẹjọ ti Hunye ro, awa naa rii pe ohun to ku diẹ kaato ni ẹsun to fi kan, bi awọn eeyan ba dibo, ti ẹ kọ odo fun iru ẹni bẹẹ, ṣe ka sọ pe ko dibo funra rẹ ni. O ni iyawo ati mọlẹbi. Ọpọ ẹri lo ko silẹ, bii bo ṣe gba fọọmu, bo ṣe ṣayẹwo oludije, ati bo ṣe kopa ninu eto idibo. Ṣugbọn gẹgẹ bii alaga, IPAC, ẹtọ mi ni lati gba a nimọran.
“O ti gba ile-ẹjọ lọ ni tootọ, ṣugbọn o tun fi ti ọmọluabi ṣe, pẹlu bi ko ṣe jẹ ki ija bẹrẹ laaarin awọn ọmọ ẹyin rẹ, ati ti awọn yooku. Iwa ọmọluabi yẹn la n tọrọ nipinlẹ Ogun.”
Bakan naa, nigba to n mẹnuba diẹ lara awọn aṣeyọri rẹ, gẹgẹ bi alaga IPAC nipinlẹ Ogun, Kọmureedi Sanyaolu sọ pe aawọ ati ija to maa n waye laaarin awọn alaga ẹgbẹ oṣelu ti di ohun igbagbe.
Sanyaolu sọ pe kii ṣe pe kii si ikunsinu gẹgẹ bi ẹlẹran-ara, ṣugbọn sibẹ, ifẹ lawọn eeyan maa n ba ara wọn lo ninu ẹgbẹ, paapaa lasiko eto oṣelu bayii.
“Bi ẹ ba wo o, latigba ti mo ti di alaga, tipatipa lẹ maa fi rii pe ija n ṣẹlẹ laaarin awọn ọmọ ẹgbẹ bii ti tẹlẹ, nitori pe nko fi aye rẹ silẹ,” o fidi rẹ mulẹ.
O kọminu lori bi ọpọ awọn oloṣelu ṣe n gboju kuro lawọn agbegbe to nilo abojuto, to si ni “eto idibo 2027 ko nii dabi ọrọ okoowo bii ti tẹlẹ.”
“Ọpọ nnkan ti mo tako ni pe, eeyan ko le di gomina nipinlẹ Ogun bi iru adije bẹẹ ba n ṣe awọn nnkan ti ko ba oju mu.
“Tipatipa lẹ maa fi ri ile iwosan to ni bọọsi meji si meji, ṣugbọn awọn to fẹẹ dije du ipo gomina, ẹlomiran ti ra bọọsi to le lọọdunrun nitori pe o fẹẹ dije. Beeyan ba le ra aduru bọọsi bẹẹ lati fi dije fun ipo gomina, ki lo de ti ko na iru owo bẹẹ lati fi ra bọọsi s’awọn ile iwosan? Mi o ka iru awọn eeyan bẹẹ gẹgẹ bi ẹni to ni nnkan gidi to fẹẹ ṣe fun araalu.
“Eeyan wa ni ipo ile igbimọ aṣofin, o kuro nibẹ, o bọ si ile igbimọ aṣoju-ṣofin, o tun ya, o bọ si sẹnetọ, o tun wa fẹẹ ṣe gomina bayii. Ẹ ko wa to ilu, ẹ wa jẹ ilu ni. Eeyan ko le na gbogbo owo to wa lọwọ ẹ lati fi ṣe ipolongo idi, ko wa debẹ tan, ka lero wi pe yoo ṣe daadaa siluu, irọ ni, ko le ṣee.
“Bo ṣe maa ri owo rẹ ni ilọpo lo ma ma wa kaakiri. Ki awọn araalu la oju wọn silẹ, ki wọn ma jẹ ki wọn fi owo ra ọja ọla lọwọ wọn.
“Ki awọn eeyan ma ṣe maa wo o pe, ẹni to lowo julọ ni ki wọ dibo yan.”
Lori yiyan adije sipo oṣelu, o ni “Gẹgẹ bi alaga IPAC, mo maa n sọ fawọn eeyan pe bi wọn ba maa mu adije, ki wọn rii daju pe ọmọ ilu ni wọn mu, nitori pe ẹni to mọ ilu, lo mọ ọna ilu. Nko lodi si oludije kankan, ṣugbọn nko nii gbaruku ti ẹni ti ko ba mọ bi omi ilu wa ṣe ri.
“Ti a ko ba tun ero wa pa, ka jọ fọwọsowọpọ lati yan ojulowo ọmọ ilu. 
“Gbogbo igba ni mo maa n sọ ọ pe igbaradi wa fun eto idibo ọdun 2027 ko le ṣiṣẹ bi awọn oludibo ko ba laju wọn silẹ lati dibo fun ẹni to yẹ
“Ka ni ọna ti wọn n gba ṣakoso IPAC lati ọdun 2003 ni emi naa tọ ni, a ko le ni aṣeyọri ti a ni lonii. Nigba t imo de, ile itura la ti n ṣe ipade, ka too bẹrẹ ipade, ọpọ lo ti maa mu ọti yo, mo si jẹ ko ye wọn pe emi ko le gba iru nnkan bẹẹ mọ. Mo sọ pe a gbọdọ wa ile ẹgbẹ.
“Ọlọrun ba mi fi aṣẹ si i lonii, ko sẹni to maa de ile ẹgbẹ IPAC, ti ko nii fi imọriri han. Temi ba wa bọ silẹ, ẹni to ba bọ sibẹ gbọdọ tẹle ilana ti mo fi silẹ ni. Bo ṣe yẹ ki ọrọ iṣejọba ri niyẹn.
“Oye yii kii ṣe oye idile. A ko le maa ba gomina nikan wi, oun naa ni awọn alatilẹyin, awọn ni aṣoju-ṣofin ati awọn aṣofin. Ipa wo ni awọn wọnyi n ko ninu idagbasoke ipinlẹ? O ye ki ipade maa wa laaarin awọn aṣoju-ṣofin ati awọn aṣofin yii loorekoore nipa idagbasoke, nitori pe awọn ni opo to di ilu mu.”

Post a Comment

0 Comments