SOWUNMI KESI IJOBA ALASE TINUBU LATI FIDI EDE ATI ASA ILE YORUBA MULE NILE EKO.

Oloye Segun Sowunmi ti sapejuwe ede  ile  Yoruba gegebi eleyi tiko   parun nitori eyin ola
    Oloye Sowunmi pe ipe lasiko ti won gbalejo awon Olootu Egbe Akoroyin lede abinibi Yoruba eeka ti lpinle Ogun ni Ile re nilu Abeokuta laipe yi, tesiwaju wipe siso ati kiko ede Yoruba ti nfere dohun igbagbe ni Ile kaaro oojiire nitori wipe awon odo iwoyi ko fi taratara so ede naa mo.
      Agba oje oselu naa wa kesi gbogbo obi ni Ile Yoruba lati rii wipe won nfi ede yi ko awon omo won ninu Ile, bakanna sini ki awon oluko paapaa ni awon Ile eko wa mu siso ede yi lokunkundun.
          Oloye Sowunmi wa to gbogbo eeka Ile ise iroyin bii Radio, Amohunmaworan ati iwe iroyin lati maa se agbelaruge ede yii loorekoore lati le jeki won wipe pataki ni ede abinibi je lagbegbe won.
      Oloye Sowunmi wa gbe osuba agbekale egbe Akoroyin lede abinibi eyi ti yoo tunbo se afihan wipe ede Yoruba kole parun mo layelaye.
       Agba oje oloselu naa wa lo asiko yi lati kesi ALASE Bola Ahmed Tinubu lati ede Yoruba pelu awon toku mule ni awon Ile eko jakejado Orile ede yii nipa gbigba awon oluko fun awon wonyi loto.
      Agba oselu naa tesiwaju nipa gbigbe sadankata fun ALASE TINUBU fun opolopo awon eto amayederun ti won sagbekale re fun gbogbo Omo Orile ede yi. Agba oloselu naa menuba edinkun  ba owo Ori, yiyo Owo iranwo Ori epo pentiro,atunse oju ona ati lila oju ona igbalode yika origin Orile ede yi, ati beebee lo laarin odun meta isakoso re, eleyi fihan wa wipe o ni idagbasoke otun fun gbogbo mutumuwa.
     Lakotan, Oloye Sowunmi wa kesi gbogbo Omo Yoruba lati rii wipe Alase Tinubu pada wole sori aga isakoso Orile ede yii nitoripe asiko wa ni a nlo, eyi yoo si tunbo fun aye lati gbele Yoruba delete ileri re.

Post a Comment

0 Comments