OGUN 2027, YAYI PALEMO IPOLONGO SIPO GOMINA, BI WON TI SE SI OLU ILE ISE RE NILU ABEOKUTA.

       Wole  Bammeke

Ogunlogo awon eniyan lokunrin lobinrin, lomode, lagba lo peju pese sibi ayeye sisi OLU ileise ipolongo adije Asofin Agba Solomon Olamilekan Adeola YAYI  eniti o ndije  labe Egbe oselu APC gegebi Gomina Ipinle yi ninu ibo odun 2027, ti o je Omo ekun idibo Iwo orun Ipinle yi Yewa Awori ti o waye ni Ibara Omida Abeokuta lojo kejila osu keje odun yi.
     Nigbati o nsoro nibe Asofin Agba Adeola dupe pupo lowo Gomina wa Omo oba Dapo Abiodun igbalaaye ati ifowosowopo re lati je oun wa gbapo Gomina Ipinle yi leyin re. Bakanna won dupe lowo gbogbo agbagba, asiwaju,ekanekan egbe awon oba alaye pelu gbogbo awon ololufe lati fun oun laaye wa gbe apoti adije  sipo Gomina Ipinle yi.
   Adije Adeola Soo di mimo wipe olu Ile ise naa wa fun gbogbo Omo egbe ti o fe ki egbe APC jawe olubori ninu idibo odun 2027, opolopo oro amoran ni won yoo maa gba lati Owo enikeni ti o ba fe idagbasoke otun . Asofin Agba Adeola wa seleri wipe oun setan lati gbesele Ilana ati ona toun ba fun ilosiwaju otun.
   Oloye Tokunbo Talabi Akowe ljoba lpinle yi ni o soju Gomina Dapo Abiodun nibe gbe osuba rabande fun Asofin Agba Adeola kiko olu Ile ise ipolongo re solu ilu Ipinle yi, Oloye Talabi so wipe tayotayo loun fi so lokan wipe Asofin Agba Adeola ti setan lati tele igbese eleyi ti Gomina Abiodun yoo fi sile fun idagbasoke Ipinle yi.
       Nibi ayeye manigbagbe naa ni a tiri Oloye Yemi Sanusi Alaga Egbe APC lpinle yi, Alhaja Kudrat Adegunwa Balogun igbakeji adije Gomina, Arabinrin Temitope Adeola Aya Adije, Alake tile Egba Oba Adedotun Aremu Gbadebo, Olu Ilaro ati olori oba tile Yewa Oba Kehinde Olugbenle, Olubara tile Ibara Oba Jeccob Omolade awon Omo igbimo Asofin Ipinle ati Abuja,awon asiwaju oselu pelu gbogbo awon afenifere.

Post a Comment

0 Comments