ILE IGBIMO ASOFIN FOWOSI AGBEKALE OFIN MARUNDINLOGOJI FUN IDAGBASOKE IPINLE OGUN.

       Olori Ile igbimo Asofin Ipinle yi Olola julo Asofin Oludaisi Elemide ti Soo di mimo wipe Ile igbimo Asofin Ipinle yi ti sagbekale ofin marundinlogoji laarin odun meta seyin wa fun mimu idagbasoke otun bara ilu ni elekajeka bii eto aabo, eko, ilera, ogbin, oro aje, ajagungbale ati beebe lo.
         Asofin Elemide  moro yi waye lasiko ti awon akoroyin lede Yoruba lo kan si won nile ise won loke Mosan Abeokuta laipe yi. Olori Asofin naa tesiwaju wipe gbogbo awon agbekale ofin yi lowulo fun gbogbo mutumuwa olugbe Ipinle yi.
       Asofin naa wa kesi gbogbo eniyan lati maa sowopo mo ijoba Ipinle yi ki won le mudunmudun oselu awaarawa. Bakanna ni ki won fi ohunkohun ti won ba kofiri re lagbegbe won to awon agbofinro leti , ki olukuluku si je alabojuto eto aabo lagbegbe won, ki won si maa dekun igbera eni ga paapaa julo loju opo ayelujara nitori opolopo eleyi ni o maa nfa ajinigbe lawujo wa.
    Lori awon Dokita wa ti won maa njapa, Olori Asofin naa ro won lati fara won bale lati jijo gbe Orile ede goke fun iran ti o nbo leyin ola.
      Lakotan, Asofin Elemide kesi gbogbo awon lati komo won daradara ki won le mowa hu lawujo wa. Asofin naa wa dupe lowo awon akoroyin ede abinibi fun bi won tise npologo eto ijoba lona ti gbogbo eniyan le gbo ti yoo ye won yekeyeke.

Post a Comment

0 Comments