Ọba Oluṣẹgun Ayinde Feyijinmi Iroko, Oniroko tilu Iroko, nijọba ibilẹ Ado-Odo-Ọta, nipinlẹ Ogun, ti sọ pe ija ilara loun ka gbogbo isokusọ tawọn kan sọ niluu naa si ati pe oun ko ri ti wọn ro, ntori bi idagbasoke yoo ṣe deba ilu naa, lati bii ọdun meje ati oṣu meloo toun ti gori itẹ awọn baba oun lo jẹ oun logun.
Kabiyesi ọhun to kọkọ di ọba niluu naa ti wọn tun pe ni Gbadewọlu akọkọ niluu Iroko sọrọ yii lakooko to n ba oniroyin wa sọrọ ni afin ẹ.
O ni, "Ko le ma ri bẹẹ, ti nnkan ba n dun, to n dun, ti ko si ọta,alatako,ọlọtẹ, ẹ sọ fun onitọhun ko yẹra ẹ wo. Nitori eeyan ko le da a tan laye yii.
"Nnkan to ba ti dara, ọpọ eeyan lo maa n hu, amọ ọpọ kọ lọ tọ si,a ko le rin, ki ori maa mi. Bi mo ṣe wa niluu Iroko,ilu baba to bi baba mi ni.ti mo n wi bẹẹ, tawọn alaalẹ si n jẹ ko ri bẹẹ.eeyan ko le daa tan, iwọnba lo le ṣe.
" Kin ni mo tun n fẹ, mo n ri atilẹyin latọdọ ọpọ araalu, gbogbo awọn abinibi ọmọ Iroko, aafin ni wọn ti n ṣe ipade, gbogbo ẹgbẹ idagbasoke niluu yii ẹyin m ni wọn wa.
"Mo ti sọ laimọye igba pe ẹni tinu ba n bi ki wọn lọ si kootu, ki wọn si mu ẹri jade, titi di akoko yii to n lọ si ọdun kẹjọ ti mo gori oye, a ko ri ẹnikẹni, ko sẹni to nigboya.
" O waa ni bawo ni alejo kan yoo ṣe fẹẹ yi itan oun pada, wọn ko le mọ ọn to oun ati pe ija ilara lo n ba wọn ja, oun si fa wọn le Ọlọrun lọwọ.
Bakan naa ni Oniroko tun mẹnuba awọn aṣeyọri to to ti ṣe latigba to ti tẹri gbade gẹgẹ bi ọba ilu naa.
O ni, bo tilẹ jẹ pe Baba oun iyẹn Baalẹ Oloogbe Oluṣọji Ajani Feyijinmi,Iroko to bi oun lọmọ atawọn baalẹ to ti jẹ tẹlẹ naa sa ipa wọn, lara ẹ ni ileewosan igbalode ti wọn kọ siluu.
O ni lọgan toun jọba ni wọn kọ ileeṣẹ ọlọpaa siluu to si jẹ ki iwa ọdaran dinku. b
Bakan naa lo ni ileewosan igbalode toun mẹnuba ti di alopati.
Ṣe lawọn gbe igbesẹ ẹdawo tawọn araalu naa ṣi ṣe atilẹyin awọn araalu taa tun ṣe gbogbo elo pataki to wulo nibẹ ni a ra sii, koda o ni alaga ijọba ibilẹ ran aṣoju wa lati wa ṣii.
Nipa ti ọna, awọn ti kọkọ kesi ijọba ṣugbọn nigba to jẹ alabaṣiṣẹ pọ ijọba fun idagbasoke ni wọn, awọn gbe igbesẹ lati da igbimọ kan silẹ tawọn pe ni ẹni tọrọ ilu dun lọkan iyẹn Concern Group, awọn lo lọ lati ojulu bọ si ojule ti wọn gba owo, tawọn fi bẹrẹ atunṣs ọna. O nijọba si ti gba lati bawọn yanju awọn ọna yooku.
Bẹẹ lo mẹnuba a pe awọn ṣi ọja fawọn araalu nitori wọn wa bawọn pe ko sbi ti wọn yoo ti ma ta ọja, laarin ọdun meje abọ yii naa ni.
O ni bakan aimọye eto ironilagbara ati ilanilọyẹ lawọn ti ṣe fawọn ọdọ tawọn ko si fawọn agbalagba naa silẹ paapaa julọ awọn arugbo atawọn opo.
Bẹẹ lo gboriyin fun Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu lori idasilẹ ọlọpaa ipilẹ kaakiri orileede yii.
O ni igbesẹ to daraju ni eyi ti yoo mu ki eto abo tun gbilẹ si lorileede yii. O waa ki wọn fun ọkan akin oṣelu ti wọn ni lati gbesẹ bẹẹ.
O sọrọ yii lakooko to n ba oniroyin sọrọ, Ọba Feyijinmi sọ pe bi a ba ni ka sọ tododo, abo onikaluku bẹrẹ lati ile.
O ni, " Mo gboṣuba o kare fun Aarẹ wa, nitori pataki ni aabo ko lorileede yii, bi ko ba si aabo, bawo la ṣe fẹẹ ṣe e.
"A gbọdọ mu aabo wa sibi to kere lati ipinlẹ de ijọba ibílẹ ati lawọn wọọdu kaakiri to fi de ọdọ awọn ọbalọba nitori awọn ọba lo mọ eeyan agbegbe ẹ.
O ṣalaye siwaju pe wọn gbọdọ fun awọn ọba laaye lati nipa pataki ninu ofin ọlọpaa ipinlẹ, nitori ilu kọọkan lo mọ bo ṣe n ṣe aabo ilu ẹ.
Kabiyesi ni, "A fẹẹ ki wọn fawọn ọba alade nipa pataki lati ko ninu ofin ọlọpaa ipinlẹ, nitori ilu kọọkan lo mọ bi wọn ṣe n ṣe aabo ilu wọn, ti wọn ni awọn bii Jagunmolu, Oluọdẹ,Akọgun gẹgẹ bi alaabo ibilẹ, iru awọn wọnyin ki wọn fun wọn laaye lati ṣiṣẹ pọ pẹlu ọlọpaa ipinlẹ".
Nigba ti Oniroko n sọ nipa ajọṣepọ to wa laarin oun ati Ọba Abdulkabir Adeyẹmi Ọbalanlẹgẹ, Ọlọta tiluu Ọta, o sọ pe bi Baba si ọmọ ni ajọṣepọ wọn ṣe danmọran ati pe awọn ti n murasilẹ fun ayẹyẹ ọjọọbi ọgọta ọdun Kabiyesi naa.



0 Comments