MO MAA PARI AKANSE ISE ONIDAGBASOKE KI O TO DI 2027.


.......Gomina Abiodun
Omo oba Dapo Abiodun Gomina Ipinle yi ti seleri wipe isakoso oun yoo pari awon Akanse ise onidagbasoke ilu yika origun merin Ipinle yi ki o to di odun 2027, bee sini oun koni deru.abuda owo ori miran Lori awon eniyan Ipinle yi.
   Gomina Abiodun eniti o nba awon eniyan soro laipe yi leyin agbekale eto isuna odun 2025 nilu Abeokuta se alaye wipe pipari awon Akanse ise yi yoo mu itesiwaju pelu agbega ba Ipinle yi bee sini yoo je aponle  ojo iwaju fun isakoso oun.
   Omo oba Abiodun wa je ko di mimo wipe eto inawo ati otito inu pelu agboye ara eni awon fi ntuko Ijoba yi ti mu Ipinle yi wa loke tente ,.eyi lo si mu ki Ipinle  yi wa nipo keta leka ipawo wole lorile ede yi.
   Gomina wa tesiwaju wipe isakoso yi ti se atunse si opolopo  ise apati ti won jogun lati owo isakoso ti to koja lo. Isakoso yi si duro sori agbekale  eto isejoba olojo gbooro 2021--2025 eyi o ro mo  oro aje , ise idagbasoke, amuludum , ilera ,eto eko ,ise ogbin.

Post a Comment

0 Comments